Numbers 32:17 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ṣugbọn àwa tìkarawa yóo di ihamọra ogun wa, a óo sì ṣáájú ogun fún àwọn yòókù títí wọn yóo fi gba ilẹ̀ ìní tiwọn. Ṣugbọn àwọn ọmọ wa yóo máa gbé ninu ìlú olódi níhìn-ín kí àwọn eniyan ilẹ̀ náà má baà yọ wọ́n lẹ́nu.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn awa tikala wa yio di ihamọra wa giri, niwaju awọn ọmọ Israeli, titi awa o fi mú wọn dé ipò wọn: awọn ọmọ wẹ́wẹ wa yio si ma gbé inu ilu olodi nitori awọn ara ilẹ na.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n àwa ṣetán láti dira ogun ṣááju àwọn ọmọ Ísírẹ́lì títí tí a yóò fi mú wọn dé ọ̀dọ̀ wọn lákokò yìí, àwọn obìnrin àti ọmọ wẹ́wẹ́ wa yóò gbé inú ìlú tí a mọ odi sí fún ìdábòbò wọn lọ́wọ́ olùgbé ilẹ̀ náà.