Numbers 32:29 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Bí àwọn ọmọ Reubẹni ati Gadi bá bá yín ré odò Jọdani kọjá láti jagun níwájú OLUWA, bí wọ́n bá sì ràn yín lọ́wọ́ láti gba ilẹ̀ náà, ẹ óo fún wọn ní ilẹ̀ Gileadi gẹ́gẹ́ bí ìní wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Mose si wi fun wọn pe, Bi awọn ọmọ Gadi ati awọn ọmọ Reubeni yio ba bá nyin gòke Jordani lọ, olukuluku ni ihamọra fun ogun, niwaju OLUWA, ti a si ṣẹ́ ilẹ na niwaju nyin; njẹ ki ẹnyin ki o fi ilẹ Gileadi fun wọn ni iní:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó wí fún wọn pé, “Tí àwọn ọmọ Gádì àti ọmọ Rúbẹ́nì, gbogbo ọkùnrin tí ó wọ ìhámọ́ra fún ogun rékọjá odò Jọ́dánì pẹ̀lú níwájú OLÚWA, nígbà tí ẹ ṣegun ilẹ̀ náà níwájú yín, Fún wọn ní ilẹ̀ Gílíádì gẹ́gẹ́ bí ìní wọn.