Numbers 32:33 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Mose bá fi ilẹ̀ Sihoni, ọba àwọn ará Amori, ilẹ̀ Ogu, ọba Baṣani ati àwọn ilẹ̀ ati àwọn ìlú tí ó yí wọn ká fún àwọn ọmọ Gadi, àwọn ọmọ Reubẹni ati ìdajì ẹ̀yà Manase ọmọ Josẹfu.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Mose si fi ilẹ-ọba Sihoni ọba awọn ọmọ Amori, ati ilẹ-ọba Ogu ọba Baṣani fun wọn, ani fun awọn ọmọ Gadi, ati fun awọn ọmọ Reubeni, ati fun àbọ ẹ̀ya Manasse ọmọ Josefu, ilẹ na, pẹlu ilu rẹ̀ li àgbegbe rẹ̀, ani ilu ilẹ na yiká.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà Mósè fún àwọn ọmọ Gádì àti àwọn ọmọ Rúbẹ́nì àti ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè ọmọ Jóṣẹ́fù ìjọba Ṣíhónì ọba àwọn ọmọ Ámórì àti ìjọba Ógù ọba Básánì ní gbogbo ilẹ̀ náà pẹ̀lú ìlú rẹ̀ àti agbégbé tí ó yí i ka.