Numbers 33:55 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ṣugbọn bí ẹ kò bá lé gbogbo àwọn ará ilẹ̀ náà kúrò, àwọn tí ó bá kù yóo di ẹ̀gún ní ojú yín ati ẹ̀gún ní ìhà yín, wọn yóo sì máa yọ yín lẹ́nu lórí ilẹ̀ náà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn bi ẹnyin kò ba lé awọn ara ilẹ na kuro niwaju nyin; yio si ṣe, awọn ti ẹnyin jẹ ki o kù ninu wọn yio di ẹgún si oju nyin, ati ẹgún si nyin ni ìha, nwọn o si ma yọ nyin lẹnu ni ilẹ na, ninu eyiti ẹnyin ngbé.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“ ‘Ṣùgbọ́n bí ẹ kò bá lé àwọn ará ilẹ̀ náà kúrò níwájú yín, àwọn tí ẹ bá jẹ́ kí ó kù yóò di ọfà nínú ojú yín, àti ẹ̀gún ní ìhà yín. Wọn yóò fún yín ní wàhálà ní ilẹ̀ náà tí ẹ̀yin yóò gbé.