Numbers 35:12 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Yóo jẹ́ ibi ààbò fún ẹni tí ó paniyan, bí arakunrin ẹni tí ó pa bá fẹ́ gbẹ̀san, nítorí pé ẹ kò gbọdọ̀ pa ẹni tí ó bá ṣèèṣì paniyan títí yóo fi dúró níwájú ìjọ eniyan Israẹli fún ìdájọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn o si jasi ilu àbo kuro lọwọ agbẹsan; ki ẹniti o pa enia ki o má ba kú titi yio fi duro niwaju ijọ awọn enia ni idajọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọn yóò jẹ́ ibi ìsásí kúrò lọ́wọ́ olùgbẹ̀san, kí ẹní tí a fi ẹ̀sùn ìpànìyàn kàn má baà kú kí ó tó dúró níwájú àwọn ìjọ àwọn ènìyàn ní ìdájọ́.