Numbers 35:15 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Wọn yóo jẹ́ ìlú ààbò fún àwọn ọmọ Israẹli tabi àwọn àlejò tí ó wà láàrin wọn. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣèèṣì paniyan lè sá lọ sibẹ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ilu mẹfa wọnyi ni yio ma jẹ́ àbo fun awọn ọmọ Israeli, ati fun alejò ati fun atipo lãrin wọn: ki olukuluku ẹniti o ba pa enia li aimọ̀ ki o le ma salọ sibẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ìlú mẹ́fà yìí yóò jẹ́ ìlú ìsásí fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, fún àlejò àti ẹnikẹ́ni tí ó bá ń gbé láàrin wọn, kí ẹnikẹ́ni tí ó bá pa ènìyàn ní àìmọ̀ sá lọ ṣíbẹ̀.