Numbers 35:2 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Pàṣẹ fún àwọn ọmọ Israẹli pé ninu ilẹ̀ ìní wọn, kí wọ́n fún àwọn ọmọ Lefi ní àwọn ìlú tí wọn yóo máa gbé, kí wọ́n sì fún wọn ní ilẹ̀ pápá yíká àwọn ìlú wọnyi.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Paṣẹ fun awọn ọmọ Israeli, ki nwọn ki o fi ilu fun awọn ọmọ Lefi ninu ipín ilẹ-iní wọn, lati ma gbé; ki ẹnyin ki o si fi ẹbẹba-ilu fun awọn ọmọ Lefi ni ilu wọnni yi wọn ká.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Pàṣẹ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láti fún àwọn Léfì ní ilẹ̀ láti gbé lára ogún tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yóò jogún. Kí ẹ sì fún wọn ní ilẹ̀ lára pápá oko tútù, káàkiri ìlú.