Numbers 35:21 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
tabi tí ó fi ọwọ́ rẹ̀ lù ú pẹlu ibinu tí ẹni náà sì kú. Apànìyàn náà yóo jẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ ìpànìyàn, yóo sì kú fún ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀. Arakunrin ẹni tí ó pa ni yóo pa apànìyàn náà nígbà tí ó bá rí i.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Tabi bi o nṣe ọtá, ti o fi ọwọ́ rẹ̀ lù u, ti on si kú: ẹniti o lù u nì pipa li a o pa a; nitoripe apania li on: agbẹsan ẹ̀jẹ ni ki o pa apania na, nigbati o ba bá a.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Tàbí pẹ̀lú ìjà gbangba lù ú pẹ̀lú ìkúùkù tí ó sì kú, pípa ni a ó pa ẹni bẹ́ẹ̀; apànìyàn ni. Olùgbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ yóò pa apànìyàn náà tí ó bá bá a.