Numbers 35:28 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
nítorí pé apànìyàn náà gbọdọ̀ dúró ní ìlú ààbò rẹ̀ títí tí olórí alufaa yóo fi kú, lẹ́yìn náà, ó lè pada sí ilẹ̀ ìní rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitoripe on iba joko ninu ilu àbo rẹ̀ titi di ìgba ikú olori alufa: ati lẹhin ikú olori alufa ki apania na ki o pada lọ si ilẹ iní rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹni tí a fi ẹ̀sùn kàn gbọdọ̀ dúró nínú ìlú ìsásí títí di ìgbà tí olórí àlùfáà bá kú; lẹ́yìn ikú olórí àlùfáà, ni ó tó lè padà sí ibi tí dúkìá rẹ̀ wà.