Numbers 35:30 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Kí ẹ tó pa ẹnikẹ́ni tí ó bá paniyan, ẹlẹ́rìí meji gbọdọ̀ jẹ́rìí sí i pé nítòótọ́ ni olúwarẹ̀ paniyan. Ẹ̀rí eniyan kan kò tó fún ẹjọ́ apànìyàn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹnikẹni ti o ba pa enia, lati ẹnu awọn ẹlẹri wá li a o pa apania na: ṣugbọn ẹlẹri kanṣoṣo ki yio jẹri si ẹnikan lati pa a.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“ ‘Ẹnikẹ́ni tí ó bá pa ènìyàn gbọdọ̀ kú gẹ́gẹ́ bí apànìyàn lórí ìjẹ́rìí àwọn ènìyàn. Ṣùgbọ́n ẹlẹ́rìí kanṣoṣo. Kì yóò jẹ́ri sí ẹnìkan láti pa.