Numbers 35:33 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Bí ẹ bá ṣe èyí, ẹ óo sọ ilẹ̀ yín di aláìmọ́ nítorí pé ìpànìyàn a máa sọ ilẹ̀ di àìmọ́. Ikú apànìyàn nìkan ni ó sì lè ṣe ètùtù fún ìwẹ̀nùmọ́ ilẹ̀ tí ó ti di àìmọ́ nípa ìpànìyàn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹnyin kò si gbọdọ bà ilẹ na jẹ́ ninu eyiti ẹnyin ngbé: nitoripe ẹ̀jẹ ama bà ilẹ jẹ́: a kò si le ṣètutu fun ilẹ nitori ẹ̀je ti a ta sinu rẹ̀, bikoṣe nipa ẹ̀jẹ ẹniti o ta a.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“ ‘Má ṣe sọ ilẹ̀ tí ẹ wà di àìmọ́. Ìtàjẹ̀ sílẹ̀ sọ ilẹ̀ náà di àìmọ́. Atúnṣe kì yóò sí fún ilẹ̀ tí a ti ta ẹ̀jẹ̀ lé lórí, àyà fi ẹ̀jẹ̀ ẹni tí ó ta á sílẹ̀.