Numbers 35:5 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Lẹ́yìn odi ìlú kọ̀ọ̀kan, kí ẹ wọn ẹgbaa igbọnwọ ní ìhà kọ̀ọ̀kan ní ìhà ìlà oòrùn, ati ìhà gúsù, ati ìhà ìwọ̀ oòrùn, ati ìhà àríwá; kí ìlú wà ní ààrin. Ilẹ̀ tí ẹ wọ̀n yìí ni yóo jẹ́ ibùjẹ fún àwọn ẹran ọ̀sìn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ki ẹnyin ki o si wọ̀n lati ẹhin ode ilu na lọ ni ìha ìla-õrùn ẹgba igbọnwọ, ati ni ìha gusù ẹgba igbọnwọ, ati ni ìha ìwọ-õrùn ẹgba igbọnwọ, ati ni ìha ariwa ẹgba igbọnwọ; ki ilu na ki o si wà lãrin. Eyi ni yio si ma ṣe ẹbẹba-ilu fun wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Lẹ́yin náà, wọn ẹgbẹ̀ẹ́dogun (3000) ẹṣẹ̀ bàtà lápá ibi ìhà ìlà oòrùn ẹgbẹ̀ẹ́dógún (3000) ẹṣẹ̀ bàtà ní ìhà gúsù, ẹgbẹ̀ẹ́dógún (3000) ní ìhà ìwọ̀ oòrùn, àríwá. Pẹ̀lú ìlú ní àárin. Wọn yóò ní agbégbé yìí gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ pápá oko tútù fún ìlú náà.