Numbers 35:6 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ninu àwọn ìlú tí ẹ óo fún àwọn ọmọ Lefi, mẹfa ninu wọn yóo jẹ́ ìlú ààbò tí ẹni tí ó bá ṣèèṣì paniyan lè sá lọ. Lẹ́yìn ìlú mẹfa yìí, ẹ óo tún fún wọn ní ìlú mejilelogoji pẹlu ilẹ̀ tí ó yí wọn ká.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati ninu ilu ti ẹnyin o fi fun awọn ọmọ Lefi, mẹfa o jẹ́ ilu àbo, ti ẹnyin o yàn fun aṣi-enia-pa, ki o le ma salọ sibẹ̀: ki ẹnyin ki o si fi ilu mejilelogoji kún wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Mẹ́fà lára ìlú tí ẹ fún àwọn ọmọ Léfì yóò jẹ́ ìlú ibi ìsásí, tí ẹni tí ó bá pa ènìyàn yóò sá sí. Ní àfikún, ẹ fún wọn ní méjìlélógójì (42) ìlú sí i.