Numbers 35:8 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Bí ilẹ̀ ìní olukuluku ẹ̀yà àwọn ọmọ Israẹli bá ti tóbi tó, bẹ́ẹ̀ ni iye ìlú tí wọn yóo fi sílẹ̀ fún àwọn ọmọ Lefi yóo pọ̀ tó.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati ilu ti ẹnyin o fi fun wọn, ki o jẹ́ ninu ilẹ-iní awọn ọmọ Israeli, lọwọ ẹniti o ní pupọ̀ lí ẹnyin o gbà pupọ̀; ṣugbọn lọwọ ẹniti o ní diẹ li ẹnyin o gbà diẹ: ki olukuluku ki o fi ninu ilu rẹ̀ fun awọn ọmọ Lefi gẹgẹ bi ilẹ-iní rẹ̀ ti o ní.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ìlú tí ẹ fún àwọn ọmọ Léfì láti ara ilẹ̀ tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jogún, olúkúlùkù kí ó fi nínú ìlú rẹ̀ fún àwọn ọmọ Léfì gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ ìní rẹ̀ tí ó ní. Gba púpọ̀ lọ́wọ́ ẹ̀yà tí ó ní púpọ̀ àti díẹ̀ lọ́wọ́ ẹ̀yà tí ó ní díẹ̀.”