Numbers 36:4 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí ọdún jubili bá kò, tí a óo dá gbogbo ilẹ̀-ìní pada fún àwọn tí wọ́n ni wọ́n, ilẹ̀-ìní àwọn ọmọbinrin Selofehadi yóo jẹ́ ti ẹ̀yà àwọn ọkọ wọn, èyí yóo sì mú kí ilẹ̀ tiwa dínkù.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati nigbati ọdún jubeli awọn ọmọ Israeli ba dé, nigbana li a o fi ilẹ-iní wọn kún ilẹ-iní ẹ̀ya ti a gbé wọn si: bẹ̃li a o si gbà ilẹ-iní wọn kuro ninu ilẹ-iní ẹ̀ya awọn baba wa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí ọdún Júbélì àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá dé, a ó pa ogún wọn pọ̀ mọ́ ẹ̀yà tí wọ́n fẹ́ wọn sí, a ó sì gba ogún ẹ̀yà wọn kúrò lọ́wọ́ babańlá wọn.”