Numbers 4:25 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn ni yóo máa ru àwọn aṣọ ìkélé tí a fi ṣe ibi mímọ́, ati Àgọ́ Àjọ pẹlu àwọn ìbòrí rẹ̀, ati awọ ewúrẹ́ tí ń dán tí wọn fi bò ó, ati aṣọ títa fún ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn ni yio si ma rù aṣọ-ikele agọ́, ati agọ́ ajọ, ibori rẹ̀, ati ibori awọ seali ti mbẹ lori rẹ̀, ati aṣọ-tita fun ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ;
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ni yóò máa ru àwọn aṣọ títa ti Àgọ́, ti Àgọ́ Ìpàdé àti ìborí rẹ̀, àti awọ ewúrẹ́ tí a fi bò ó, aṣọ títa ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Ìpàdé,