Numbers 4:41 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Èyí ni iye àwọn tí Mose ati Aaroni kà ninu àwọn ọmọ Geriṣoni tí wọ́n lè ṣiṣẹ́ ninu Àgọ́ Àjọ gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Wọnyi li awọn ti a kà ni idile awọn ọmọ Gerṣoni, gbogbo awọn ti o ṣe iṣẹ-ìsin ninu agọ́ ajọ, ti Mose ati Aaroni kà gẹgẹ bi aṣẹ OLUWA.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èyí jẹ́ àpapọ̀ iye àwọn ọmọ Gásónì, àwọn tó ṣiṣẹ́ ní Àgọ́ Ìpàdé. Mósè àti Árónì se bí àṣẹ OLÚWA.