Numbers 4:49 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Mose ka àwọn eniyan náà, ó sì yan iṣẹ́ fún olukuluku wọn gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí OLUWA pa fún un.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Gẹgẹ bi aṣẹ OLUWA li a kà wọn nipa ọwọ́ Mose, olukuluku nipa iṣẹ-ìsin rẹ̀, ati gẹgẹ bi ẹrù rẹ̀: bẹ̃li a ti ọwọ́ rẹ̀ kà wọn, bi OLUWA ti fi aṣẹ fun Mose.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọ́n yan iṣẹ́ àti àwọn ohun tí ẹni kọ̀ọ̀kan yóò máa gbé fún un gẹ́gẹ́ bí OLÚWA ti pàṣẹ láti ẹnu Mósè. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe kà wọ́n gẹ́gẹ́ bí OLÚWA ti pàṣẹ fún Mósè.