Numbers 4:7 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Wọn yóo da aṣọ aláwọ̀ aró bo tabili tí burẹdi ìfihàn máa ń wà lórí rẹ̀. Lẹ́yìn náà, wọn yóo kó àwọn nǹkan wọnyi lé e lórí: àwọn àwo turari, àwọn àwokòtò, ati àwọn ìgò fún ọtí ìrúbọ. Burẹdi ìfihàn sì gbọdọ̀ wà lórí rẹ̀ nígbà gbogbo.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati lori tabili àkara ifihàn nì, ki nwọn ki o nà aṣọ alaró kan si, ki nwọn ki o si fi awopọkọ sori rẹ̀, ati ṣibi ati awokòto, ati ìgo ohun didà: ati àkara ìgbagbogbo nì ki o wà lori rẹ̀:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Lórí tabilì ìfihàn ni kí wọn ó na aṣọ aláró kan sí, wọn ó sì kó àwọn àwo, páànù, àwokòtò àti ìgò fún ọrẹ ohun mímu; àkàrà tó sì máa ń wà níbẹ̀ ní gbogbo ìgbà náà gbọ́dọ̀ wà níbẹ̀.