Numbers 5:19 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà náà ni alufaa yóo mú kí obinrin náà búra, yóo wí fún un pé, ‘Bí ọkunrin kankan kò bá bá ọ lòpọ̀, tí o kò sì ṣe aiṣootọ sí ọkọ rẹ, ègún inú omi kíkorò yìí kò ní ṣe ọ́ ní ibi.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Alufa na yio si mu u bura, yio si wi fun obinrin na pe, Bi ọkunrin kò ba bá ọ dàpọ, bi iwọ kò ba si yàsapakan si ìwa-aimọ́, labẹ ọkọ rẹ, ki iwọ ki o yege omi kikorò yi ti imú egún wá:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àlùfáà yóò sì mú obìnrin náà búra, yóò wí pé, “Bí ọkùnrin mìíràn kò bá bá ọ lòpọ̀, tí ó kò sì yapa, tí o kò sì di aláìmọ́ níwọ̀n ìgbà tí ó wà lábẹ́ àṣẹ ọkọ rẹ̀, a jẹ́ pé omi kíkorò tí ń mú ègún wá yìí kò ní se ọ́ níbi.