Numbers 5:21 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
kí OLUWA sọ ọ́ di ẹni ègún ati ẹni ìfibú láàrin àwọn eniyan rẹ̀. Kí OLUWA mú kí abẹ́ rẹ rà, kí ó sì mú kí ara rẹ wú.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana ni ki alufa ki o mu ki obinrin na fi èpe bura, ki alufa ki o si wi fun obinrin na pe, Ki OLUWA ki o sọ ọ di ẹni egún, ati ẹni ifire ninu awọn enia rẹ, nigbati OLUWA ba mu itan rẹ rà, ti o si mu inu rẹ wú;
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
nígbà náà ni àlùfáà yóò mú obìnrin náà búra, yóò sọ fún obìnrin náà pé: “Kí OLÚWA sọ ọ́ di ẹni ègún àti ẹni ìbáwí láàrin àwọn ènìyàn rẹ nípa mímú kí itan rẹ jẹrà, kí ikùn rẹ sì wú.