Numbers 5:27 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Bí ó bá jẹ́ pé obinrin náà ti ṣe alaiṣootọ sí ọkọ rẹ̀, tí ọkunrin mìíràn bá ti bá a lòpọ̀, omi náà yóo korò ninu rẹ̀, yóo sì mú kí inú rẹ̀ wú, kí abẹ́ rẹ̀ sì rà. Yóo sì fi bẹ́ẹ̀ di ẹni ègún láàrin àwọn eniyan rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati o ba si mu omi na tán, yio si ṣe, bi o ba ṣe ẹni ibàjẹ́, ti o si ṣẹ̀ ọkọ rẹ̀, omi ti imú egún wá yio si wọ̀ inu rẹ̀ lọ, a si di kikorò, inu rẹ̀, a si wú, itan rẹ̀ a si rà: obinrin na a si di ẹni egún lãrin awọn enia rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bí ó bá ti mú obìnrin yìí mu omi náà, bí ó bá sì jẹ́ pé obìnrin náà ti ba ara rẹ̀ jẹ́, tí ó sì se àìsòótọ́ sí ọkọ rẹ̀, omi tí ń mú ègún wá, yóò wọ ara rẹ̀, yóò fa ìrora kíkorò fún un, ikùn rẹ̀ yóò wú, itan rẹ̀ yóò sì jẹrà dànù, yóò sì di ẹni ègún láàrin àwọn ènìyàn rẹ̀.