Numbers 5:30 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
tabi nígbà tí ọkunrin kan bá ń ṣiyèméjì nípa ìdúró iyawo rẹ̀, ọkunrin náà yóo mú iyawo rẹ̀ wá siwaju OLÚWA, alufaa yóo sì ṣe gbogbo ohun tí mo pa láṣẹ yìí.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Tabi nigbati ẹmi owú ba dé si ọkọ kan, ti o ba si njowú obinrin rẹ̀; nigbana yio mu obinrin na duro niwaju OLUWA, ki alufa ki o si ṣe gbogbo ofin yi si i.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Tàbí nígbà tí ẹ̀mí owú jíjẹ bá bà lé ọkùnrin kan nítorí pé ó fura sí ìyàwó rẹ̀. Àlùfáà yóò mú obìnrin náà dúró níwájú OLÚWA yóò sì ṣe gẹ́gẹ́ bí òfin ti wí fún un.