Numbers 5:8 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣugbọn bí ẹni tí ó ṣẹ̀ náà bá ti kú, tí kò sì ní ìbátan tí ó lè gba owó ìtanràn náà, kí ó san owó náà fún àwọn alufaa OLUWA. Lẹ́yìn èyí ni yóo mú àgbò wá fún ẹbọ ètùtù ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bi o ba si ṣepe ọkunrin na kò ní ibatan kan lati san ẹsan ẹ̀ṣẹ na fun, ki a san ẹsan na fun OLUWA, ani fun alufa; pẹlu àgbo ètutu, ti a o fi ṣètutu fun u.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n bí irú ẹni bẹ́ẹ̀ kò bá ní ìbátan tí ó sún mọ́ ọn tí ó lè ṣe àtúnṣe àṣìṣe rẹ̀ náà fún, àtúnṣe náà jẹ́ ti OLÚWA, ẹ sì gbọdọ̀ ko fún àlùfáà pẹ̀lú àgbò tí a fi ṣe ètùtù fún ẹni náà