Numbers 6:17 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Yóo fi àgbò náà rú ẹbọ alaafia sí OLUWA pẹlu burẹdi agbọ̀n kan tí kò ní ìwúkàrà ninu. Alufaa yóo fi ohun jíjẹ ati ohun mímu rẹ̀ rúbọ pẹlu.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ki o si ru àgbo na li ẹbọ alafia si OLUWA, pẹlu agbọ̀n àkara alaiwu: ki alufa pẹlu ki o si ru ẹbọ ohunjijẹ rẹ̀, ati ẹbọ ohunmimu rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àlùfáà yóò fi àgbò náà rú ẹbọ àlàáfíà sí OLÚWA, pẹ̀lú apẹ̀rẹ̀ àkàrà tí kò ní ìwúkàrà; yóò rú ẹbọ ohun jíjẹ àti ọrẹ ohun mímu.