Numbers 6:19 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Alufaa yóo fún Nasiri náà ní apá àgbò tí a ti bọ̀ pẹlu burẹdi dídùn kan tí kò ní ìwúkàrà ninu, ati burẹdi fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ kan tí kò ní ìwúkàrà ninu, lẹ́yìn ìgbà tí ó bá ti fá irun orí rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ki alufa ki o si mú apá bibọ̀ àgbo na, ati àkara adidùn kan alaiwu kuro ninu agbọ̀n na, ati àkara fẹlẹfẹlẹ kan alaiwu, ki o si fi wọn lé ọwọ́ Nasiri na, lẹhin ìgba ti a fá irun ori ìyasapakan rẹ̀ tán:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“ ‘Lẹ́yìn tí Násírì bá ti fá irun ìyàsọ́tọ̀ rẹ̀ tan, àlùfáà yóò mú apá àgbò bíbọ̀, àkàrà aláìwú kan àti àkàrà fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ tí kò ní ìwúkàrà láti inú apẹ̀rẹ̀ yóò sì kó gbogbo rẹ̀ lé e lọ́wọ́.