Numbers 6:20 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Lẹ́yìn náà ni alufaa yóo fi àwọn ẹbọ náà níwájú OLUWA. Mímọ́ ni wọ́n jẹ́ fún alufaa náà, pẹlu àyà tí a fì ati itan tí wọ́n fi rúbọ. Lẹ́yìn èyí, Nasiri náà lè máa mu ọtí waini.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ki alufa ki o si fì wọn li ẹbọ fifì niwaju OLUWA: mimọ́ li eyi fun alufa na, pẹlu àiya fifì, ati itan agbesọsoke: lẹhin na Nasiri na le ma mu ọti-waini.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àlùfáà yóò fí gbogbo rẹ̀ níwájú OLÚWA gẹ́gẹ́ bí ẹbọ fífì, wọ́n jẹ́ mímọ́, wọ́n sì jẹ́ ti àlùfáà pẹ̀lú ìgẹ̀ tí a fì àti itan tí wọ́n mú wá. Lẹ́yìn èyi, Násírì náà lè mu wáìnì.