Numbers 7:41 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Lẹ́yìn náà, Ṣelumieli, ọmọ Suriṣadai tún ko akọ mààlúù meji, àgbò marun-un, òbúkọ marun-un, ati akọ ọ̀dọ́ aguntan marun-un ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan kalẹ̀ fún ẹbọ alaafia.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati fun ẹbọ ti ẹbọ alafia, akọmalu meji, àgbo marun, obukọ marun, akọ ọdọ-agutan marun ọlọdún kan: eyi li ọrẹ-ẹbọ Ṣelumieli ọmọ Ṣuriṣaddai.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Màlúù méjì, àgbò márùn-ún, akọ ewúrẹ́ márùn-ún àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn ọlọ́dún kan márùn-ún tí wọn ó fi rú ẹbọ àlàáfíà. Èyí ni ọrẹ Sélúmíélì ọmọ Surisádáì.