Numbers 7:85 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
ìwọ̀n àwo fadaka kọ̀ọ̀kan jẹ́ aadoje (130) ṣekeli; ìwọ̀n gbogbo àwọn abọ́ fadaka náà jẹ́ ẹgbaa ṣekeli ó lé irinwo (2,400). Ìwọ̀n tí wọn ń lò ní ibi mímọ́ ni wọ́n fi wọ̀n wọ́n.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awopọkọ fadakà kọkan jẹ́ ãdoje ṣekeli: awokòto kọkan jẹ́ ãdọrin: gbogbo ohun-èlo fadakà jẹ́ egbejila ṣekeli, gẹgẹ bi ṣekeli ibi-mimọ́;
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwo fàdákà kọ̀ọ̀kan wọn àádóje (130) ṣékélì, àwokòtò kọ̀ọ̀kan sì wọn àádọ́rin (70). Àpapọ̀ gbogbo àwo fàdákà jẹ́ egbèjìlá ṣékélì (2,400) gẹ́gẹ́ bí iye owó ibi mímọ́.