Numbers 7:89 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí Mose wọ inú àgọ́ ìpàdé lọ láti bá OLUWA sọ̀rọ̀, ó gbọ́ ohùn kan tí ń bá a sọ̀rọ̀ láti orí ìtẹ́ àánú tí ó wà lórí àpótí ẹ̀rí, láàrin àwọn kerubu mejeeji. Ẹni náà bá Mose sọ̀rọ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati Mose si wọ̀ inu agọ́ ajọ lọ lati bá a (Ọlọrun) sọ̀rọ, nigbana li o gbọ́ ohùn ti nfọ̀ si i lati ori itẹ́-ãnu nì wá ti mbẹ lori apoti ẹrí, lati agbedemeji awọn kerubu meji nì wá: o si bá a sọ̀rọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí Mósè wọ inú Àgọ́ Ìpàdé láti bá OLÚWA sọ̀rọ̀, OLÚWA sì sọ̀rọ̀ sí i láti àárin àwọn kérúbù méjì láti orí ìtẹ́ àánú tó bo àpótí ẹ̀rí, ohùn náà sì bá Mósè sọ̀rọ̀.