Numbers 8:21 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àwọn ọmọ Lefi wẹ ara wọn mọ́ kúrò ninu ẹ̀ṣẹ̀, wọ́n sì fọ aṣọ wọn. Aaroni yà wọ́n sọ́tọ̀ gẹ́gẹ́ bí ọrẹ fífì fún OLUWA, ó sì ṣe ètùtù fún wọn láti wẹ̀ wọ́n mọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn ọmọ Lefi si wẹ̀ ara wọn mọ́ kuro ninu ẹ̀ṣẹ, nwọn si fọ̀ aṣọ wọn; Aaroni si mú wọn wá li ọrẹ fifì siwaju OLUWA: Aaroni si ṣètutu fun wọn lati wẹ̀ wọn mọ́.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ọmọ Léfì wẹ ara wọn mọ́, wọ́n sì fọ aṣọ wọn. Árónì sì mú wọn wá gẹ́gẹ́ bí ọrẹ fífì níwájú OLÚWA, Árónì sì ṣe ètùtù fún wọn láti wẹ̀ wọ́n mọ́.