Numbers 9:10 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, nígbà tí ọ̀kan ninu yín tabi àwọn ọmọ yín bá di aláìmọ́ nítorí pé ó fi ọwọ́ kan òkú; tabi ó wà ní ìrìn àjò, ṣugbọn tí ọkàn rẹ̀ sì fẹ́ ṣe Àjọ̀dún ìrékọjá.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Sọ fun awọn ọmọ Israeli pe, Bi ẹnikẹni ninu nyin, tabi ninu iran nyin, ba ti ipa okú di alaimọ́, tabi bi o ba wà li ọ̀na àjo jijìn rére, sibẹ̀ on o pa ajọ irekọja mọ́ fun OLUWA.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Sọ fún àwọn ará Ísírẹ́lì: ‘Bí ẹnìkan nínú yín tàbí nínú ìran yín bá di aláìmọ́ nípa òkú ènìyàn tàbí bí ó bá lọ sí ìrìnàjò síbẹ̀ yóò pa àjọ Ìrékọjá mọ́.