Numbers 9:12 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ẹ kò gbọdọ̀ fi àjẹkù kankan sílẹ̀ di ọjọ́ keji, ẹ kò sì gbọdọ̀ fọ́ ọ̀kankan ninu egungun ẹran tí ẹ bá fi rú ẹbọ náà. Ẹ óo ṣe ọdún Àjọ̀dún Ìrékọjá náà gẹ́gẹ́ bí òfin ati ìlànà rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ki nwọn ki o máṣe kùsilẹ ninu rẹ̀ titi di owurọ̀, bẹ̃ni nwọn kò gbọdọ fọ́ egungun rẹ̀ kan: gẹgẹ bi gbogbo ìlana irekọja ni ki nwọn ki o ṣe e.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọn kò gbọdọ̀ ṣẹ́ ọ̀kankan kù di àárọ̀, wọn kò sì gbọdọ̀ ṣẹ́ eegun rẹ̀. Wọ́n gbọdọ̀ tẹ̀lé gbogbo ìlànà fún ṣíṣẹ àjọ Ìrékọjá.