Numbers 9:14 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Bí àlejò kan bá wà ní ààrin yín tí ó sì fẹ́ ṣe Àjọ̀dún Ìrékọjá, yóo ṣe é gẹ́gẹ́ bí òfin ati ìlànà rẹ̀. Òfin ati ìlànà kan náà ni ó wà fún gbogbo yín, ati onílé ati àlejò.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bi alejò kan ba si nṣe atipo lọdọ nyin, ti o si nfẹ́ pa irekọja mọ́ fun OLUWA; gẹgẹ bi ìlana irekọja, ati gẹgẹ bi aṣẹ rẹ̀, ni ki o ṣe bẹ̃: ìlana kan ni ki ẹnyin ki o ní, ati fun alejò, ati fun ibilẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“ ‘Bí àlejò tí ń gbé láàrin yín bá fẹ́ ṣe Àjọ Ìrékọjá ó gbọdọ̀ pa á mọ́ ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà àti òfin rẹ̀. Ìlànà kan náà ni kí ẹ ní fún àlejò àti àwọn ọmọ bíbí ilẹ̀ yín.’ ”