Numbers 9:15 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ní ọjọ́ tí wọn pa Àgọ́ Àjọ, èyí tí í ṣe Àgọ́ Ẹ̀rí, ìkùukùu bò ó. Ní alẹ́, ìkùukùu náà dàbí ọ̀wọ̀n iná.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati li ọjọ́ ti a gbé agọ́ ró awọsanma si bò agọ́ na, eyinì ni, agọ́ ẹrí: ati li alẹ o si hàn lori agọ́ na bi iná, titi o fi di owurọ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní ọjọ́ tí wọ́n gbé àgọ́, èyí tí í ṣe àgọ́ ẹ̀rí, dúró, ìkúùkù àwọ̀sánmọ̀ bò ó mọ́lẹ̀. Ìkúùkù náà sì dàbí iná lórí àgọ́ láti ìrọ̀lẹ́ títí di òwúrọ̀.