Numbers 9:18 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àṣẹ OLUWA ni àwọn ọmọ Israẹli ń tẹ̀lé láti tú àgọ́ wọn palẹ̀ ati láti tún àgọ́ wọn pa. Níwọ̀n ìgbà tí ìkùukùu náà bá ti wà ní orí Àgọ́ Àjọ, àwọn ọmọ Israẹli yóo dúró ninu àgọ́ wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nipa aṣẹ OLUWA awọn ọmọ Israeli a ṣí, nipa aṣẹ OLUWA nwọn a si dó: ni gbogbo ọjọ́ ti awọsanma ba simi lori agọ́ na, nwọn a dó.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nípa àṣẹ OLÚWA ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń jáde lọ, nípa àṣẹ OLÚWA náà sì ni wọ́n ń pa ibùdó wọn. Nígbà tí ìkúùkù bá dúró sórí àgọ́, àwọn náà yóò dúró sí ibùdó.