Numbers 9:19 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà tí ìkùukùu náà tilẹ̀ dúró pẹ́ ní orí Àgọ́, àwọn ọmọ Israẹli ṣe ìgbọràn sí OLUWA, wọ́n dúró ninu àgọ́ wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati awọsanma ba si pẹ li ọjọ́ pupọ̀ lori agọ́ na, awọn ọmọ Israeli a si ma ṣe afiyesi aṣẹ OLUWA, nwọn ki si iṣi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí ìkúùkù bá dúró sórí àgọ́ fún ìgbà pípẹ́, síbẹ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbọ́ràn sí àṣẹ OLÚWA wọn kò sì ní gbéra láti lọ.