Numbers 9:20 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ìgbà mìíràn ẹ̀wẹ̀, ìkùukùu náà yóo dúró lórí Àgọ́ Àjọ fún ọjọ́ bíi mélòó péré. Sibẹsibẹ, àṣẹ OLUWA ni àwọn ọmọ Israẹli ń tẹ̀lé kì báà ṣe pé ó jẹ mọ́ pé kí wọn tú àgọ́ wọn palẹ̀ ni tabi pé kí wọ́n tún un pa.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigba miran awọsanma a wà li ọjọ́ diẹ lori agọ́ na; nigbana gẹgẹ bi aṣẹ OLUWA nwọn a dó, gẹgẹ bi aṣẹ OLUWA nwọn a si ṣí.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ìgbà mìíràn ìkúùkù lè wà lórí àgọ́ fún ọjọ́ díẹ̀; ṣíbẹ̀ ní àṣẹ OLÚWA, wọn yóò dúró ní ibùdó, bí ó sì tún yá, ní àṣẹ rẹ̀ náà ni wọn yóò gbéra.