Numbers 9:21 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà mìíràn, ìkùukùu náà lè má dúró lórí Àgọ́ Àjọ ju àṣáálẹ́ títí di òwúrọ̀ lọ, sibẹsibẹ, nígbàkúùgbà tí ìkùukùu bá kúrò lórí Àgọ́ Àjọ ni àwọn ọmọ Israẹli máa ń tẹ̀síwájú.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigba miran awọsanma a duro lati alẹ titi di owurọ̀; nigbati awọsanma si ṣí soke li owurọ̀, nwọn a ṣí: iba ṣe li ọsán tabi li oru, ti awọsanma ba ká soke, nwọn a ṣí.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ìgbà mìíràn ìkúùkù lè dúró láti ìrọ̀lẹ́ di àárọ̀, nígbà tó bá sì kúrò ní àárọ̀, wọn ó gbéra. Ìbá à ṣe ní ọ̀sán tàbí òru, ìgbàkigbà tí ìkúùkù bá tó kúrò náà ni wọn ó tó gbéra.