Numbers 9:22 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Kì báà sì jẹ́ ọjọ́ meji ni, tabi oṣù kan, tabi ọdún kan tabi jù bẹ́ẹ̀ lọ, níwọ̀n ìgbà tí ìkùukùu náà bá sì wà ní orí Àgọ́ Àjọ, wọn yóo dúró ni. Ṣugbọn bí ó bá ti gbéra ni àwọn náà yóo tẹ̀síwájú.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bi ijọ́ meji ni, tabi oṣù kan, tabi ọdún kan, ti awọsanma ba pẹ lori agọ́ na, ti o simi lé e, awọn ọmọ Israeli a dó, nwọn ki si iṣí: ṣugbọn nigbati o ba ká soke, nwọn a ṣí.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ìbá à ṣe fún ọjọ́ méjì, oṣù kan tàbí ọdún kan ni ìkúùkù fi dúró sórí àgọ́, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yóò dúró ní ibùdó wọn, wọn ò ní í gbéra; ṣùgbọ́n nígbà tí ó bá lọ sókè ni wọn ó tó o gbéra.