Numbers 9:23 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí OLUWA bá fún wọn láṣẹ ni wọ́n máa ń pàgọ́, nígbà tí ó bá sì tó fún wọn láṣẹ ni wọ́n tó máa ń gbéra.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nipa aṣẹ OLUWA nwọn a dó, ati nipa aṣẹ OLUWA nwọn a ṣí: nwọn a ma ṣe afiyesi aṣẹ OLUWA, gẹgẹ bi ọ̀rọ OLUWA nipa ọwọ́ Mose.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nípa àṣẹ OLÚWA ni wọ́n ń pa ibùdó wọn, nípa àṣẹ OLÚWA náà sì ni wọ́n ń gbéra. Wọ́n gbọ́ràn sí àṣẹ OLÚWA ní ìbámu pẹ̀lú àṣẹ OLÚWA láti ẹnu Mósè.