Numbers 9:7 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Nítòótọ́, a ti di aláìmọ́ nítorí pé a fi ọwọ́ kan òkú, ṣugbọn kí ló dé tí a kò fi lè mú ọrẹ ẹbọ wa wá fún OLUWA gẹ́gẹ́ bí àwọn arakunrin wa?”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn ọkunrin na si wi fun u pe, Awa ti ipa okú ọkunrin kan di alaimọ́: nitori kili a o ṣe fàsẹhin ti awa ki o le mú ọrẹ-ẹbọ OLUWA wá li akokò rẹ̀ pẹlu awọn ọmọ Israeli?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọ́n sọ fún Mósè pé, “A di aláìmọ́ nípa òkú ènìyàn, ṣùgbọ́n kí ló dé tí a kò fi ní í le è fi ọrẹ wa fún OLÚWA pẹ̀lú àwọn ará Ísírẹ́lì yòókù ní àsìkò tí a ti yàn.”