Obadiah 1:11 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ní ọjọ́ tí àwọn ọ̀tá ń kó ọrọ̀ wọn lọ, tí àwọn àjèjì wọ inú ìlú wọn, tí àwọn ọ̀tá sì ń ṣẹ́ gègé lórí Jerusalẹmu, ẹ dúró, ẹ̀ ń wò wọ́n; ẹ sì dàbí ọ̀kan ninu wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ni ọjọ ti iwọ duro li apa keji, ni ọjọ ti awọn alejo kó awọn ogun rẹ̀ ni igbèkun lọ, ti awọn ajeji si wọ inu ibode rẹ̀, ti nwọn si ṣẹ keké lori Jerusalemu, ani iwọ wà bi ọkan ninu wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní ọjọ́ tí ìwọ dúró ní apákan, ní ọjọ́ tí àlejò kó ogún rẹ lọ, tí àwọn àjèjì sì wọ ibodè rẹ tí wọ́n sì sẹ́ kèké lórí Jérúsálẹ́mù, ìwọ náà wà bí ọ̀kan nínú wọn.