Obadiah 1:18 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ilé Jakọbu yóo dàbí iná, ilé Josẹfu yóo dàbí ọ̀wọ́ iná, ilé Esau yóo sì dàbí àgékù koríko. Wọn yóo jó ilé Esau; àwọn ìran Esau yóo jó àjórun láìku ẹnìkan; nítorí pé OLUWA ló sọ bẹ́ẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ile Jakobu yio si jẹ iná, ati ile Josefu ọwọ́-iná, ati ile Esau fun akeku-koriko, nwọn o si ràn ninu wọn, nwọn o si run wọn; kì yio si sí ẹniti yio kù ni ile Esau: nitori Oluwa ti wi i.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ilé Jákọ́bù yóò sì jẹ́ iná àti ilé Jósẹ́fù ọwọ́ iná ilé Ísọ̀ yóò jẹ àkékù koríko wọn yóò fi iná sí i, wọn yóò jo run. Kì yóò sí ẹni tí yóò kù ní ilé Ísọ̀.” Nítorí OLÚWA ti wí i.