Obadiah 1:4 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Bí o tilẹ̀ fò lọ sókè bí ẹyẹ idì, tí ó tẹ́ ìtẹ́ rẹ̀ sí ààrin àwọn ìràwọ̀, láti òkè náà ni n óo ti fà ọ́ lulẹ̀. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bi iwọ tilẹ gbe ara rẹ ga bi idì, ati bi iwọ tilẹ tẹ́ itẹ rẹ sãrin awọn irawọ, lati ibẹ li emi o ti sọ̀ ọ kalẹ, ni Oluwa wi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bí ìwọ tilẹ̀ gbé ara rẹ ga bí ẹyẹ idì, Bí ìwọ tilẹ̀ tẹ́ ìtẹ́ rẹ sí àárin àwọn ìràwọ̀, Láti ibẹ̀ ni èmi yóò ti sọ̀ ọ kalẹ̀,” ni OLÚWA wí.