Philippians 1:20 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
gẹ́gẹ́ bí igbẹkẹle ati ìrètí mi pé n kò ní rí ohun ìtìjú kan. Ṣugbọn bí mo ti máa ń gbé Kristi ga ninu ara mi pẹlu ìgboyà nígbà gbogbo, bẹ́ẹ̀ gan-an náà ni n óo tún máa gbé e ga nisinsinyii ìbáà jẹ́ pé mo wà láàyè tabi pé mo kú.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Gẹgẹ bi ìnàgà ati ireti mi pe ki oju ki o máṣe tì mi li ohunkohun, ṣugbọn pẹlu igboiya gbogbo, bi nigbagbogbo, bẹ̃ nisisiyi pẹlu a o gbé Kristi ga lara mi, ibã ṣe nipa ìye, tabi nipa ikú.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó jẹ́ ìfojúsọ́nà àti ìrètí mi pé ojú kì yóò tì mí nínú ohunkóhun, ṣùgbọ́n èmi ó ní ìgboyà nísinsìnyìí bí ti ìgbà gbogbo pé ní yíyè, tàbí ní kíkú, a ó gbé ga lára mi.