Philippians 2:30 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nítorí pé ó fẹ́rẹ̀ kú nítorí iṣẹ́ Kristi. Ó fi ẹ̀mí rẹ̀ wéwu, kí ó lè rọ́pò yín ninu ohun tí ó kù tí ó yẹ kí ẹ ṣe gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ fún mi.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitoripe nitori iṣẹ Kristi li o ṣe sunmọ ẹnu-ọ̀na ikú, ti kò si kà ẹmí ara rẹ̀ si, lati mu aitó iṣẹ isin nyin si mi kun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí iṣẹ́ Kírísítì ni ó ṣe súnmọ́ ẹnu-ọ̀nà ikú, tí ó sì fi ẹ̀mí ara rẹ̀ wé wu, láti mu àìtó iṣẹ́ ìsìn yín sí mi kún.