Philippians 4:12 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Mo mọ bí eniyan ti ń gbé ìgbé-ayé ninu àìní, mo sì mọ bí eniyan ti ń gbé ìgbé-ayé ninu ọpọlọpọ ọrọ̀. Nípòkípò tí mo bá wà, ninu ohun gbogbo, mo ti kọ́ àṣírí bí a ti ń ní ìtẹ́lọ́rùn, kì báà jẹ́ ninu ebi tabi ayo, ninu ọ̀pọ̀ tabi àìní.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Mo mọ̀ bi ã ti iṣe di rirẹ̀-silẹ, mo mọ bi ã ti iṣe di pupọ: li ohunkohun ati li ohun gbogbo mo ti kọ́ aṣiri ati mã jẹ ajẹyó ati lati wà li aijẹ, lati mã ni anijù ati lati ṣe alaini.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Mo mọ̀ bí a ti ṣe ń rẹ ara sílẹ̀, mo sì mọ̀ bí a ti ń di púpọ̀: ni ohunkóhun àti ní ohun gbogbo mo ti kọ́ àṣírí láti máa jẹ́ àjẹyó àti láti wà ni àìjẹ, láti máa ni ànító àti láti ṣe aláìní.