Proverbs 27:22 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Wọn ì báà ju òmùgọ̀ sinu odó, kí wọn fi ọmọ odó gún un pọ̀ mọ́ ọkà, ẹnìkan kò lè gba ìwà òmùgọ̀ lọ́wọ́ rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bi iwọ tilẹ fi ọmọri-odó gún aṣiwère ninu odo larin alikama, wère rẹ̀ kì yio fi i silẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bí a tilẹ̀ gún aláìgbọ́n nínú odó, fi ọmọ odó gún-un bí èlùbọ́ ìwọ kì yóò le è yọ ìwà òmùgọ̀ rẹ̀ kúrò ní inú rẹ̀.