Proverbs 28:12 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà tí olódodo bá borí, àwọn eniyan á yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀, ṣugbọn nígbà tí ìkà bá dìde, àwọn eniyan á sá pamọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati awọn olododo enia ba nyọ̀, ọṣọ́ nla a wà; ṣugbọn nigbati enia buburu ba dide, enia a sá pamọ́.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí olódodo ń lékè ariwo ayọ̀ ta; ṣùgbọ́n nígbà tí ènìyàn búburú gorí òye, àwọn ènìyàn a na pápá bora.